Native Bible

Nahum 3:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara, èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà.

Nahum 3:6 in English

Nahum 3:6 · Berean Standard Bible

I will pelt you with filth and treat you with contempt; I will make a spectacle of you.

Context

4Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ panṣágà àgbèrè tí ó rójú rere gbà, ìyá àjẹ́ tí ó ṣọ́ àwọn Orílẹ̀-èdè di ẹrú nípa àgbèrè rẹ̀ àti àwọn ìdílé nípa ìṣe àjẹ́ rẹ̀. 5“Èmi dojúkọ ọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi ó si ká aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ ní ojú rẹ. Èmi yóò sì fi ìhòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè àti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba. 6Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara, èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà. 7Gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé, ‘Ninefe ṣòfò, ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’ Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?” 8Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Tebesi lọ, èyí tí ó wà ní ibi odò Naili, tí omi sì yí káàkiri? Odò náà sì jẹ́ ààbò rẹ̀, omi si jẹ́ odi rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.