Nahumu 3:8
Nahum 3:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Tebesi lọ, èyí tí ó wà ní ibi odò Naili, tí omi sì yí káàkiri? Odò náà sì jẹ́ ààbò rẹ̀, omi si jẹ́ odi rẹ̀.
Nahum 3:8 in English
Nahum 3:8 · Berean Standard Bible
Are you better than Thebes,* stationed by the Nile with water around her, whose rampart was the sea, whose wall was the water?
Context
6Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara,
èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́,
èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà. 7Gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé,
‘Ninefe ṣòfò, ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’
Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?” 8Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Tebesi lọ,
èyí tí ó wà ní ibi odò Naili,
tí omi sì yí káàkiri?
Odò náà sì jẹ́ ààbò rẹ̀,
omi si jẹ́ odi rẹ̀. 9Etiopia àti Ejibiti ni agbára rẹ, kò sí ní òpin;
Puti àti Libia ni àwọn olùgbèjà rẹ̀. 10Síbẹ̀síbẹ̀ a kó o ní ìgbèkùn
o sì lọ sí oko ẹrú.
Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ̀ ni a ó fọ́ mọ́lẹ̀
ní orí ìta gbogbo ìgboro.
Wọ́n sì di ìbò nítorí àwọn ọlọ́lá rẹ̀ ọkùnrin,
gbogbo àwọn ọlọ́lá rẹ ni a sì fi ẹ̀wọ̀n dè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.