Native Bible

Nahum 3:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé, ‘Ninefe ṣòfò, ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’ Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?”

Nahum 3:7 in English

Nahum 3:7 · Berean Standard Bible

Then all who see you will recoil from you and say, ‘Nineveh is devastated; who will grieve for her?’ Where can I find comforters for you?”

Context

5“Èmi dojúkọ ọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi ó si ká aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ ní ojú rẹ. Èmi yóò sì fi ìhòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè àti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba. 6Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara, èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà. 7Gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé, ‘Ninefe ṣòfò, ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’ Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?” 8Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn ju Tebesi lọ, èyí tí ó wà ní ibi odò Naili, tí omi sì yí káàkiri? Odò náà sì jẹ́ ààbò rẹ̀, omi si jẹ́ odi rẹ̀. 9Etiopia àti Ejibiti ni agbára rẹ, kò sí ní òpin; Puti àti Libia ni àwọn olùgbèjà rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.