Nahumu 3:5
Nahum 3:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi dojúkọ ọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Èmi ó si ká aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ ní ojú rẹ. Èmi yóò sì fi ìhòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè àti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba.
Nahum 3:5 in English
Nahum 3:5 · Berean Standard Bible
“Behold, I am against you,” declares the LORD of Hosts. “I will lift your skirts over your face. I will show your nakedness to the nations and your shame to the kingdoms.
Context
3Ológun orí ẹṣin ń fi ìgbónára
ju idà wọn mọ̀nàmọ́ná
ọ̀kọ̀ rẹ̀ ti ń dán yanran sí òkè!
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ si ní àwọn ẹni tí a pa,
àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú;
òkú kò sì ni òpin;
àwọn ènìyàn sì ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú. 4Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ panṣágà
àgbèrè tí ó rójú rere gbà,
ìyá àjẹ́ tí ó ṣọ́ àwọn Orílẹ̀-èdè di ẹrú
nípa àgbèrè rẹ̀
àti àwọn ìdílé nípa ìṣe àjẹ́ rẹ̀. 5“Èmi dojúkọ ọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Èmi ó si ká aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ ní ojú rẹ.
Èmi yóò sì fi ìhòhò rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè
àti ìtìjú rẹ̀ han àwọn ilẹ̀ ọba. 6Èmi yóò da ẹ̀gbin tí ó ni ìríra sí ọ ní ara,
èmi yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́,
èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà. 7Gbogbo àwọn tí ó ba sì wò ọ́ yóò sì káàánú fún ọ, wọn yóò sì wí pé,
‘Ninefe ṣòfò, ta ni yóò kẹ́dùn rẹ?’
Níbo ni èmi o ti wá olùtùnú fún ọ?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.