Ẹkún Jeremiah 3:22
Lamentations 3:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.
Lamentations 3:22 in English
Lamentations 3:22 · Berean Standard Bible
Because of the loving devotion * of the LORD we are not consumed, for His mercies never fail.
Context
20Mo ṣèrántí wọn,
ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi. 21Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn
àti nítorí náà ní mo nírètí. 22Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,
nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà. 23Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;
títóbi ni òdodo rẹ̀. 24Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa;
nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.