Jeremiah 50:36
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Idà lórí àwọn wòlíì èké wọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun, wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù.
Jeremiah 50:36 in English
Jeremiah 50:36 · Berean Standard Bible
A sword is against her false prophets, and they will become fools. A sword is against her warriors, and they will be filled with terror.
Context
34Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára,
Olúwa Ọlọ́run Alágbára ni orúkọ rẹ̀.
Yóò sì gbe ìjà wọn jà,
kí ó ba à lè mú wọn wá sinmi ní ilẹ̀ náà;
ṣùgbọ́n kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Babeli. 35“Idà lórí àwọn Babeli!”
ni Olúwa wí,
“lòdì sí àwọn tó ń gbé ní Babeli,
àwọn aláṣẹ àti àwọn amòye ọkùnrin. 36Idà lórí àwọn wòlíì èké
wọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun,
wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù. 37Idà lórí àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀
àti àwọn àjèjì nínú ẹgbẹ́ rẹ̀.
Wọn yóò di obìnrin.
Idà lórí àwọn ohun ìṣúra rẹ̀! 38Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ.
Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère,
àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.