Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára, Olúwa Ọlọ́run Alágbára ni orúkọ rẹ̀. Yóò sì gbe ìjà wọn jà, kí ó ba à lè mú wọn wá sinmi ní ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Babeli.

Jeremiah 50:34 in English

Jeremiah 50:34 · Berean Standard Bible

Their Redeemer is strong; the LORD of Hosts is His name. He will fervently plead their case so that He may bring rest to the earth, but turmoil to those who live in Babylon.

Context

32Onígbèéraga yóò kọsẹ̀, yóò sì ṣubú, kì yóò sì ṣí ẹni tí yóò gbé dìde. Èmi yóò tan iná ní ìlú náà, èyí tí yóò sì jo run.” 33Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: “A pọ́n àwọn ènìyàn Israẹli lójú àti àwọn ènìyàn Juda pẹ̀lú. Gbogbo àwọn tí ó kó wọn nígbèkùn dì wọn mú ṣinṣin wọn kò sì jẹ́ kí ó sá àsálà. 34Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára, Olúwa Ọlọ́run Alágbára ni orúkọ rẹ̀. Yóò sì gbe ìjà wọn jà, kí ó ba à lè mú wọn wá sinmi ní ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Babeli. 35“Idà lórí àwọn Babeli!” ni Olúwa wí, “lòdì sí àwọn tó ń gbé ní Babeli, àwọn aláṣẹ àti àwọn amòye ọkùnrin. 36Idà lórí àwọn wòlíì èké wọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun, wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.