Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Idà lórí àwọn Babeli!” ni Olúwa wí, “lòdì sí àwọn tó ń gbé ní Babeli, àwọn aláṣẹ àti àwọn amòye ọkùnrin.

Jeremiah 50:35 in English

Jeremiah 50:35 · Berean Standard Bible

A sword is against the Chaldeans, declares the LORD, against those who live in Babylon, and against her officials and wise men.

Context

33Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: “A pọ́n àwọn ènìyàn Israẹli lójú àti àwọn ènìyàn Juda pẹ̀lú. Gbogbo àwọn tí ó kó wọn nígbèkùn dì wọn mú ṣinṣin wọn kò sì jẹ́ kí ó sá àsálà. 34Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára, Olúwa Ọlọ́run Alágbára ni orúkọ rẹ̀. Yóò sì gbe ìjà wọn jà, kí ó ba à lè mú wọn wá sinmi ní ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Babeli. 35“Idà lórí àwọn Babeli!” ni Olúwa wí, “lòdì sí àwọn tó ń gbé ní Babeli, àwọn aláṣẹ àti àwọn amòye ọkùnrin. 36Idà lórí àwọn wòlíì èké wọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun, wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù. 37Idà lórí àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ àti àwọn àjèjì nínú ẹgbẹ́ rẹ̀. Wọn yóò di obìnrin. Idà lórí àwọn ohun ìṣúra rẹ̀!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.