Jeremiah 50:38
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ. Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère, àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.
Jeremiah 50:38 in English
Jeremiah 50:38 · Berean Standard Bible
A drought is upon her waters, and they will be dried up. For it is a land of graven images, and the people go mad over idols.*
Context
36Idà lórí àwọn wòlíì èké
wọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun,
wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù. 37Idà lórí àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀
àti àwọn àjèjì nínú ẹgbẹ́ rẹ̀.
Wọn yóò di obìnrin.
Idà lórí àwọn ohun ìṣúra rẹ̀! 38Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ.
Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère,
àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù. 39“Nítorí náà àwọn ẹranko ijù
pẹ̀lú ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀,
abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀,
a kì yóò sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé,
bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran. 40Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti gba ìjọba Sodomu àti Gomorra
pẹ̀lú àwọn ìlú agbègbè wọn,”
ni Olúwa wí,
“torí náà kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé ibẹ̀;
ènìyàn ki yóò gbé nínú rè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.