Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nítorí náà àwọn ẹranko ijù pẹ̀lú ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀, abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀, a kì yóò sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran.

Jeremiah 50:39 in English

Jeremiah 50:39 · Berean Standard Bible

So the desert creatures and hyenas will live there and ostriches * will dwell there. It will never again be inhabited or lived in from generation to generation.

Context

37Idà lórí àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ àti àwọn àjèjì nínú ẹgbẹ́ rẹ̀. Wọn yóò di obìnrin. Idà lórí àwọn ohun ìṣúra rẹ̀! 38Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ. Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère, àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù. 39“Nítorí náà àwọn ẹranko ijù pẹ̀lú ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀, abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀, a kì yóò sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran. 40Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti gba ìjọba Sodomu àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú agbègbè wọn,” ni Olúwa wí, “torí náà kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé ibẹ̀; ènìyàn ki yóò gbé nínú rè. 41“Wò ó! Ọ̀wọ́ ọmọ-ogun láti ìhà àríwá; orílẹ̀-èdè ńlá àti àwọn ọba púpọ̀ ni à ń gbé dìde láti òpin ilẹ̀ ayé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.