Jeremiah 48:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Níwọ́n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ, a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn, Kemoṣi náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀.
Jeremiah 48:7 in English
Jeremiah 48:7 · Berean Standard Bible
Because you trust in your works and treasures, you too will be captured, and Chemosh will go into exile with his priests and officials.
Context
5Wọ́n gòkè lọ sí Luhiti,
wọ́n ń sọkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ;
ní ojú ọ̀nà sí Horonaimu
igbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ. 6Sá! Àsálà fún ẹ̀mí yín;
kí ẹ sì dàbí aláìní ní aginjù. 7Níwọ́n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ,
a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn,
Kemoṣi náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn
pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀. 8Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ,
ìlú kan kò sì ní le là.
Àfonífojì yóò di ahoro
àti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run,
nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀. 9Fi iyọ̀ sí Moabu,
nítorí yóò ṣègbé,
àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoro
láìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.