Jeremiah 48:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fi iyọ̀ sí Moabu, nítorí yóò ṣègbé, àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoro láìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀.
Jeremiah 48:9 in English
Jeremiah 48:9 · Berean Standard Bible
Put salt on Moab, for she will be laid waste;* her cities will become desolate, with no one to dwell in them.
Context
7Níwọ́n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ,
a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn,
Kemoṣi náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn
pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀. 8Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ,
ìlú kan kò sì ní le là.
Àfonífojì yóò di ahoro
àti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run,
nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀. 9Fi iyọ̀ sí Moabu,
nítorí yóò ṣègbé,
àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoro
láìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀. 10“Ìfibú ni fún ẹni tí ó fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ Olúwa,
ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀. 11“Moabu ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá
bí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀,
tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejì
kò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí.
Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ,
òórùn rẹ̀ kò yí padà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.