Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ, ìlú kan kò sì ní le là. Àfonífojì yóò di ahoro àti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run, nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

Jeremiah 48:8 in English

Jeremiah 48:8 · Berean Standard Bible

The destroyer will move against every city, and not one town will escape. The valley will also be ruined, and the high plain will be destroyed, as the LORD has said.

Context

6Sá! Àsálà fún ẹ̀mí yín; kí ẹ sì dàbí aláìní ní aginjù. 7Níwọ́n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ, a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn, Kemoṣi náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀. 8Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ, ìlú kan kò sì ní le là. Àfonífojì yóò di ahoro àti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run, nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀. 9Fi iyọ̀ sí Moabu, nítorí yóò ṣègbé, àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoro láìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀. 10“Ìfibú ni fún ẹni tí ó fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ Olúwa, ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.