Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Sá! Àsálà fún ẹ̀mí yín; kí ẹ sì dàbí aláìní ní aginjù.

Jeremiah 48:6 in English

Jeremiah 48:6 · Berean Standard Bible

‘Flee! Run for your lives! Become like a juniper in the desert.*’

Context

4Moabu yóò di wíwó palẹ̀; àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta. 5Wọ́n gòkè lọ sí Luhiti, wọ́n ń sọkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ; ní ojú ọ̀nà sí Horonaimu igbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ. 6Sá! Àsálà fún ẹ̀mí yín; kí ẹ sì dàbí aláìní ní aginjù. 7Níwọ́n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ, a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn, Kemoṣi náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀. 8Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ, ìlú kan kò sì ní le là. Àfonífojì yóò di ahoro àti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run, nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.