Jeremiah 48:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Moabu yóò di wíwó palẹ̀; àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta.
Jeremiah 48:4 in English
Jeremiah 48:4 · Berean Standard Bible
Moab will be shattered; her little ones will cry out.*
Context
2Moabu kò ní ní ìyìn mọ́,
ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀,
‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’
Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́,
a ó fi idà lé e yín. 3Gbọ́ igbe ní Horonaimu,
igbe ìrora àti ìparun ńlá. 4Moabu yóò di wíwó palẹ̀;
àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta. 5Wọ́n gòkè lọ sí Luhiti,
wọ́n ń sọkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ;
ní ojú ọ̀nà sí Horonaimu
igbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ. 6Sá! Àsálà fún ẹ̀mí yín;
kí ẹ sì dàbí aláìní ní aginjù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.