Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbọ́ igbe ní Horonaimu, igbe ìrora àti ìparun ńlá.

Jeremiah 48:3 in English

Jeremiah 48:3 · Berean Standard Bible

A voice cries out from Horonaim: ‘Devastation and great destruction!’

Context

1Nípa Moabu. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: “Ègbé ni fún Nebo nítorí a ó parun. A dójútì Kiriataimu, a sì mú un, ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká. 2Moabu kò ní ní ìyìn mọ́, ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀, ‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’ Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́, a ó fi idà lé e yín. 3Gbọ́ igbe ní Horonaimu, igbe ìrora àti ìparun ńlá. 4Moabu yóò di wíwó palẹ̀; àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta. 5Wọ́n gòkè lọ sí Luhiti, wọ́n ń sọkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ; ní ojú ọ̀nà sí Horonaimu igbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.