Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Moabu kò ní ní ìyìn mọ́, ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀, ‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’ Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́, a ó fi idà lé e yín.

Jeremiah 48:2 in English

Jeremiah 48:2 · Berean Standard Bible

There is no longer praise for Moab; in Heshbon * they devise evil against her: ‘Come, let us cut her off from nationhood.’ You too, O people of Madmen,* will be silenced; the sword will pursue you.

Context

1Nípa Moabu. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: “Ègbé ni fún Nebo nítorí a ó parun. A dójútì Kiriataimu, a sì mú un, ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká. 2Moabu kò ní ní ìyìn mọ́, ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀, ‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’ Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́, a ó fi idà lé e yín. 3Gbọ́ igbe ní Horonaimu, igbe ìrora àti ìparun ńlá. 4Moabu yóò di wíwó palẹ̀; àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.