Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídè ń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Moabu,” ní Olúwa wí.

Jeremiah 48:43 in English

Jeremiah 48:43 · Berean Standard Bible

Terror and pit and snare await you, O dweller of Moab,” declares the LORD.

Context

41Kerioti ni a ó kó lẹ́rú àti ilé agbára ni ó gbà. Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn akọni Moabu yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí. 42A ó pa Moabu run gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè nítorí pé ó gbéraga sí Olúwa. 43Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídè ń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Moabu,” ní Olúwa wí. 44“Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fún ẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìn ẹnikẹ́ni tí o bá jáde síta nínú ọ̀fìn ní à ó mú nínú okùn dídè nítorí tí èmi yóò mú wá sórí Moabu àní ọdún ìjìyà rẹ,” ní Olúwa wí. 45“Ní abẹ́ òjìji Heṣboni àwọn tí ó sá dúró láìní agbára, nítorí iná ti jáde wá láti Heṣboni, àti ọwọ́ iná láti àárín Sihoni, yóò sì jó iwájú orí Moabu run, àti agbárí àwọn ọmọ aláriwo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.