Jeremiah 48:42
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A ó pa Moabu run gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè nítorí pé ó gbéraga sí Olúwa.
Jeremiah 48:42 in English
Jeremiah 48:42 · Berean Standard Bible
Moab will be destroyed as a nation because he vaunted himself against the LORD.
Context
40Báyìí ni Olúwa wí:
“Wò ó ẹyẹ idì náà ń fò bọ̀ nílẹ̀
ó sì na ìyẹ́ rẹ̀ lórí Moabu. 41Kerioti ni a ó kó lẹ́rú àti ilé agbára ni ó gbà.
Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn akọni Moabu
yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí. 42A ó pa Moabu run gẹ́gẹ́ bí
orílẹ̀-èdè nítorí pé ó gbéraga sí Olúwa. 43Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídè
ń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Moabu,”
ní Olúwa wí. 44“Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fún
ẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìn
ẹnikẹ́ni tí o bá jáde síta
nínú ọ̀fìn ní à ó mú
nínú okùn dídè nítorí tí
èmi yóò mú wá sórí
Moabu àní ọdún ìjìyà rẹ,”
ní Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.