Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kerioti ni a ó kó lẹ́rú àti ilé agbára ni ó gbà. Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn akọni Moabu yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí.

Jeremiah 48:41 in English

Jeremiah 48:41 · Berean Standard Bible

Kirioth has been taken, and the strongholds seized. In that day the heart of Moab’s warriors will be like the heart of a woman in labor.

Context

39“Èéṣe tí ẹ fi fọ́ túútúú, tí ẹ sì fi ń pohùnréré ẹkún! Báwo ni Moabu ṣe yí ẹ̀yìn padà ní ìtìjú! Moabu ti di ẹni ìtìjú àti ẹ̀gàn àti ìdààmú sí gbogbo àwọn tí ó yìí ká.” 40Báyìí ni Olúwa wí: “Wò ó ẹyẹ idì náà ń fò bọ̀ nílẹ̀ ó sì na ìyẹ́ rẹ̀ lórí Moabu. 41Kerioti ni a ó kó lẹ́rú àti ilé agbára ni ó gbà. Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn akọni Moabu yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí. 42A ó pa Moabu run gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè nítorí pé ó gbéraga sí Olúwa. 43Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídè ń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Moabu,” ní Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.