Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ní abẹ́ òjìji Heṣboni àwọn tí ó sá dúró láìní agbára, nítorí iná ti jáde wá láti Heṣboni, àti ọwọ́ iná láti àárín Sihoni, yóò sì jó iwájú orí Moabu run, àti agbárí àwọn ọmọ aláriwo.

Jeremiah 48:45 in English

Jeremiah 48:45 · Berean Standard Bible

“Those who flee will stand helpless in Heshbon’s shadow, because fire has gone forth from Heshbon and a flame from within Sihon. It devours the foreheads of Moab and the skulls of the sons of tumult.

Context

43Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídè ń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Moabu,” ní Olúwa wí. 44“Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fún ẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìn ẹnikẹ́ni tí o bá jáde síta nínú ọ̀fìn ní à ó mú nínú okùn dídè nítorí tí èmi yóò mú wá sórí Moabu àní ọdún ìjìyà rẹ,” ní Olúwa wí. 45“Ní abẹ́ òjìji Heṣboni àwọn tí ó sá dúró láìní agbára, nítorí iná ti jáde wá láti Heṣboni, àti ọwọ́ iná láti àárín Sihoni, yóò sì jó iwájú orí Moabu run, àti agbárí àwọn ọmọ aláriwo. 46Ègbé ní fún ọ Moabu! Àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè Kemoṣi ṣègbé a kó àwọn ọmọkùnrin rẹ lọ sí ilẹ̀ àjèjì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ sí ìgbèkùn. 47“Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ Moabu padà ní ọjọ́ ìkẹyìn,” ni Olúwa wí. Eléyìí ní ìdájọ́ ìkẹyìn lórí Moabu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.