Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kò sí ohun tí Ejibiti le ṣe— orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò.

Isaiah 19:15 in English

Isaiah 19:15 · Berean Standard Bible

There is nothing Egypt can do— head or tail, palm or reed.

Context

13Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè, a ti tan àwọn ọmọ-aládé Memfisi jẹ; àwọn òkúta igun ilé tí í ṣe ti ẹ̀yà rẹ ti ṣi Ejibiti lọ́nà. 14Olúwa ti da ẹ̀mí òòyì sínú wọn; wọ́n mú Ejibiti ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú ohun gbogbo tí ó ń ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú èébì rẹ̀. 15Kò sí ohun tí Ejibiti le ṣe— orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò. 16Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Ejibiti yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn. 17Ilẹ̀ Juda yóò sì di ẹ̀rù fún Ejibiti; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Juda létí wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbèrò láti ṣe sí wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.