Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa ti da ẹ̀mí òòyì sínú wọn; wọ́n mú Ejibiti ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú ohun gbogbo tí ó ń ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú èébì rẹ̀.

Isaiah 19:14 in English

Isaiah 19:14 · Berean Standard Bible

The LORD has poured into her a spirit of confusion. Egypt has been led astray in all she does, as a drunkard staggers through his own vomit.

Context

12Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí? Jẹ́ kí wọn fihàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mí mọ̀ ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pinnu lórí Ejibiti. 13Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè, a ti tan àwọn ọmọ-aládé Memfisi jẹ; àwọn òkúta igun ilé tí í ṣe ti ẹ̀yà rẹ ti ṣi Ejibiti lọ́nà. 14Olúwa ti da ẹ̀mí òòyì sínú wọn; wọ́n mú Ejibiti ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú ohun gbogbo tí ó ń ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú èébì rẹ̀. 15Kò sí ohun tí Ejibiti le ṣe— orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò. 16Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Ejibiti yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.