Isaiah 19:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè, a ti tan àwọn ọmọ-aládé Memfisi jẹ; àwọn òkúta igun ilé tí í ṣe ti ẹ̀yà rẹ ti ṣi Ejibiti lọ́nà.
Isaiah 19:13 in English
Isaiah 19:13 · Berean Standard Bible
The princes of Zoan have become fools; the princes of Memphis * are deceived. The cornerstones of her tribes have led Egypt astray.
Context
11Àwọn oníṣẹ́ Ṣoani ti di aláìgbọ́n,
àwọn ọlọ́gbọ́n olùdámọ̀ràn Farao
ń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá.
Báwo ló ṣe lè sọ fún Farao pé,
“Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn,
ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba àtijọ́.” 12Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí?
Jẹ́ kí wọn fihàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mí mọ̀
ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ti pinnu lórí Ejibiti. 13Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè,
a ti tan àwọn ọmọ-aládé Memfisi jẹ;
àwọn òkúta igun ilé tí í ṣe ti ẹ̀yà rẹ
ti ṣi Ejibiti lọ́nà. 14Olúwa ti da ẹ̀mí òòyì sínú wọn;
wọ́n mú Ejibiti ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú
ohun gbogbo tí ó ń ṣe,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú èébì rẹ̀. 15Kò sí ohun tí Ejibiti le ṣe—
orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.