Isaiah 19:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn oníṣẹ́ Ṣoani ti di aláìgbọ́n, àwọn ọlọ́gbọ́n olùdámọ̀ràn Farao ń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá. Báwo ló ṣe lè sọ fún Farao pé, “Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba àtijọ́.”
Isaiah 19:11 in English
Isaiah 19:11 · Berean Standard Bible
The princes of Zoan are mere fools; Pharaoh’s wise counselors give senseless advice. How can you say to Pharaoh, “I am one of the wise, a son of eastern kings”?
Context
9Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú
àwọn ahunṣọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù. 10Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì,
gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìsàn ọkàn yóò ṣe. 11Àwọn oníṣẹ́ Ṣoani ti di aláìgbọ́n,
àwọn ọlọ́gbọ́n olùdámọ̀ràn Farao
ń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá.
Báwo ló ṣe lè sọ fún Farao pé,
“Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn,
ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba àtijọ́.” 12Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí?
Jẹ́ kí wọn fihàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mí mọ̀
ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ti pinnu lórí Ejibiti. 13Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè,
a ti tan àwọn ọmọ-aládé Memfisi jẹ;
àwọn òkúta igun ilé tí í ṣe ti ẹ̀yà rẹ
ti ṣi Ejibiti lọ́nà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.