Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí? Jẹ́ kí wọn fihàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mí mọ̀ ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pinnu lórí Ejibiti.

Isaiah 19:12 in English

Isaiah 19:12 · Berean Standard Bible

Where are your wise men now? Let them tell you and reveal what the LORD of Hosts has planned against Egypt.

Context

10Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì, gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìsàn ọkàn yóò ṣe. 11Àwọn oníṣẹ́ Ṣoani ti di aláìgbọ́n, àwọn ọlọ́gbọ́n olùdámọ̀ràn Farao ń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá. Báwo ló ṣe lè sọ fún Farao pé, “Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba àtijọ́.” 12Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí? Jẹ́ kí wọn fihàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mí mọ̀ ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pinnu lórí Ejibiti. 13Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè, a ti tan àwọn ọmọ-aládé Memfisi jẹ; àwọn òkúta igun ilé tí í ṣe ti ẹ̀yà rẹ ti ṣi Ejibiti lọ́nà. 14Olúwa ti da ẹ̀mí òòyì sínú wọn; wọ́n mú Ejibiti ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú ohun gbogbo tí ó ń ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú èébì rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.