Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ilẹ̀ Juda yóò sì di ẹ̀rù fún Ejibiti; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Juda létí wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbèrò láti ṣe sí wọn.

Isaiah 19:17 in English

Isaiah 19:17 · Berean Standard Bible

The land of Judah will bring terror to Egypt; whenever Judah is mentioned, Egypt will tremble over what the LORD of Hosts has planned against it.

Context

15Kò sí ohun tí Ejibiti le ṣe— orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò. 16Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Ejibiti yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn. 17Ilẹ̀ Juda yóò sì di ẹ̀rù fún Ejibiti; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Juda létí wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbèrò láti ṣe sí wọn. 18Ní ọjọ́ náà ìlú márùn-ún ní ilẹ̀ Ejibiti yóò sọ èdè àwọn ará Kenaani, wọn yóò sì búra àtìlẹ́yìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun. 19Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún Olúwa ní àárín gbùngbùn Ejibiti, àti ọ̀wọ́n kan fún Olúwa ní etí bodè rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.