Native Bible

Habakkuk 3:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já, ó sì da àwọn omi ńlá ru.

Habakkuk 3:15 in English

Habakkuk 3:15 · Berean Standard Bible

You trampled the sea with Your horses, churning the great waters.

Context

13Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, àti láti gba ẹni àmì òróró rẹ là, Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀. 14Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde láti tú wá ká, ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ tálákà run ní ìkọ̀kọ̀. 15Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já, ó sì da àwọn omi ńlá ru. 16Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì, ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà; ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ, ẹsẹ̀ mi sì wárìrì, mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá. 17Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná, tí èso kò sí nínú àjàrà; tí igi olifi ko le so, àwọn oko ko sì mú oúnjẹ wá; tí a sì ké agbo ẹran kúrò nínú agbo, tí kò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùso mọ́,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.