Habakuku 3:14
Habakkuk 3:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde láti tú wá ká, ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ tálákà run ní ìkọ̀kọ̀.
Habakkuk 3:14 in English
Habakkuk 3:14 · Berean Standard Bible
With his own spear You pierced his head, when his warriors stormed out to scatter us, gloating as though ready to secretly devour the weak.
Context
12Ní ìrunú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já,
ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ. 13Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,
àti láti gba ẹni àmì òróró rẹ là,
Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀. 14Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ
nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀
jáde láti tú wá ká,
ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ tálákà run ní ìkọ̀kọ̀. 15Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já,
ó sì da àwọn omi ńlá ru. 16Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì,
ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà;
ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ,
ẹsẹ̀ mi sì wárìrì,
mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú
láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.