Habakuku 3:16
Habakkuk 3:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì, ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà; ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ, ẹsẹ̀ mi sì wárìrì, mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.
Habakkuk 3:16 in English
Habakkuk 3:16 · Berean Standard Bible
I heard and trembled within; my lips quivered at the sound. Decay entered my bones; I trembled where I stood. Yet I must wait patiently for the day of distress to come upon the people who invade us.
Context
14Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ
nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀
jáde láti tú wá ká,
ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ tálákà run ní ìkọ̀kọ̀. 15Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já,
ó sì da àwọn omi ńlá ru. 16Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì,
ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà;
ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ,
ẹsẹ̀ mi sì wárìrì,
mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú
láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá. 17Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná,
tí èso kò sí nínú àjàrà;
tí igi olifi ko le so,
àwọn oko ko sì mú oúnjẹ wá;
tí a sì ké agbo ẹran kúrò nínú agbo,
tí kò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùso mọ́, 18síbẹ̀, èmi ó láyọ̀ nínú Olúwa,
èmi yóò sí máa yọ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.