Native Bible

Habakkuk 3:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, àti láti gba ẹni àmì òróró rẹ là, Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀.

Habakkuk 3:13 in English

Habakkuk 3:13 · Berean Standard Bible

You went forth for the salvation of Your people, to save Your anointed. You crushed the head of the house of the wicked and stripped him from head to toe. Selah

Context

11Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ ni ibùgbé wọn, pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ, àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà. 12Ní ìrunú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já, ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ. 13Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, àti láti gba ẹni àmì òróró rẹ là, Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀. 14Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde láti tú wá ká, ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ tálákà run ní ìkọ̀kọ̀. 15Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já, ó sì da àwọn omi ńlá ru.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.