Native Bible

Habakkuk 3:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ ni ibùgbé wọn, pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ, àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà.

Habakkuk 3:11 in English

Habakkuk 3:11 · Berean Standard Bible

Sun and moon stood still in their places at the flash of Your flying arrows, at the brightness of Your shining spear.

Context

9A ṣí ọrun rẹ sílẹ̀ pátápátá, gẹ́gẹ́ bí ìbúra àwọn ẹ̀yà, àní ọ̀rọ̀ rẹ, ìwọ sì fi odò pín ilẹ̀ ayé. 10Àwọn òkè ńlá ri ọ wọn sì wárìrì àgbàrá òjò ń sàn án kọjá lọ; ibú ń ké ramúramù ó sì gbé irú omi sókè. 11Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ ni ibùgbé wọn, pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ, àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà. 12Ní ìrunú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já, ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ. 13Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, àti láti gba ẹni àmì òróró rẹ là, Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.