Esekiẹli 21:27
Ezekiel 21:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìparun! Ìparun! Èmi yóò ṣé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò ṣe pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fi fún.’
Ezekiel 21:27 in English
Ezekiel 21:27 · Berean Standard Bible
A ruin, a ruin, I will make it a ruin! And it will not be restored until the arrival of Him to whom it belongs, to whom I have assigned the right of judgment.*’
Context
25“ ‘Ìwọ aláìmọ́ àti ẹni búburú ọmọ-aládé Israẹli, ẹni ti ọjọ́ rẹ̀ ti dé, ẹni tí àsìkò ìjìyà rẹ̀ ti dé góńgó, 26èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀, ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀. 27Ìparun! Ìparun! Èmi yóò ṣé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò ṣe pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fi fún.’ 28“Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nípa àwọn ará Ammoni àti àbùkù wọn:
“ ‘Idà kan idà kan
tí á fa yọ fún ìpànìyàn
tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò
àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná! 29Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí èké nípa yín
àti àfọ̀ṣẹ èké nípa yín
a yóò gbé e lé àwọn ọrùn
ènìyàn búburú ti a ó pa,
àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé,
àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.