Native Bible

Ezekiel 21:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀, ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀.

Ezekiel 21:26 in English

Ezekiel 21:26 · Berean Standard Bible

This is what the Lord GOD says: ‘Remove the turban, and take off the crown. Things will not remain as they are: Exalt the lowly and bring low the exalted.

Context

24“Nítorí náà èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí ti ẹ̀yin ti mú ẹ̀bi yín wá sí ìrántí nípa ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba, ní ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí, a yóò mú yín ní ìgbèkùn. 25“ ‘Ìwọ aláìmọ́ àti ẹni búburú ọmọ-aládé Israẹli, ẹni ti ọjọ́ rẹ̀ ti dé, ẹni tí àsìkò ìjìyà rẹ̀ ti dé góńgó, 26èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀, ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀. 27Ìparun! Ìparun! Èmi yóò ṣé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò ṣe pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fi fún.’ 28“Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nípa àwọn ará Ammoni àti àbùkù wọn: “ ‘Idà kan idà kan tí á fa yọ fún ìpànìyàn tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.