Esekiẹli 21:28
Ezekiel 21:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nípa àwọn ará Ammoni àti àbùkù wọn: “ ‘Idà kan idà kan tí á fa yọ fún ìpànìyàn tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná!
Ezekiel 21:28 in English
Ezekiel 21:28 · Berean Standard Bible
Now prophesy, son of man, and declare that this is what the Lord GOD says concerning the Ammonites and their contempt: ‘A sword! A sword is drawn for slaughter, polished to consume, to flash like lightning—
Context
26èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀, ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀. 27Ìparun! Ìparun! Èmi yóò ṣé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò ṣe pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fi fún.’ 28“Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nípa àwọn ará Ammoni àti àbùkù wọn:
“ ‘Idà kan idà kan
tí á fa yọ fún ìpànìyàn
tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò
àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná! 29Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí èké nípa yín
àti àfọ̀ṣẹ èké nípa yín
a yóò gbé e lé àwọn ọrùn
ènìyàn búburú ti a ó pa,
àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé,
àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó. 30“ ‘Dá idà padà sínú àkọ̀ rẹ̀.
Níbi tí a gbé ṣẹ̀dá yín,
ní ibi tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.