Native Bible

Ezekiel 21:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí èké nípa yín àti àfọ̀ṣẹ èké nípa yín a yóò gbé e lé àwọn ọrùn ènìyàn búburú ti a ó pa, àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé, àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó.

Ezekiel 21:29 in English

Ezekiel 21:29 · Berean Standard Bible

while they offer false visions for you and lying divinations about you— to be placed on the necks of the wicked who are slain, whose day has come, the time of their final punishment.

Context

27Ìparun! Ìparun! Èmi yóò ṣé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò ṣe pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fi fún.’ 28“Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nípa àwọn ará Ammoni àti àbùkù wọn: “ ‘Idà kan idà kan tí á fa yọ fún ìpànìyàn tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná! 29Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí èké nípa yín àti àfọ̀ṣẹ èké nípa yín a yóò gbé e lé àwọn ọrùn ènìyàn búburú ti a ó pa, àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé, àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó. 30“ ‘Dá idà padà sínú àkọ̀ rẹ̀. Níbi tí a gbé ṣẹ̀dá yín, ní ibi tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ wá. 31Níbẹ̀ ni èmi yóò ti ṣe ìdájọ́ yín, èmi o sì fi èémí ìbínú gbígbóná mi bá yín jà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.