Native Bible

Ezekiel 21:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Dá idà padà sínú àkọ̀ rẹ̀. Níbi tí a gbé ṣẹ̀dá yín, ní ibi tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ wá.

Ezekiel 21:30 in English

Ezekiel 21:30 · Berean Standard Bible

Return the sword to its sheath! In the place where you were created, in the land of your origin, I will judge you.

Context

28“Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nípa àwọn ará Ammoni àti àbùkù wọn: “ ‘Idà kan idà kan tí á fa yọ fún ìpànìyàn tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná! 29Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí èké nípa yín àti àfọ̀ṣẹ èké nípa yín a yóò gbé e lé àwọn ọrùn ènìyàn búburú ti a ó pa, àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé, àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó. 30“ ‘Dá idà padà sínú àkọ̀ rẹ̀. Níbi tí a gbé ṣẹ̀dá yín, ní ibi tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ wá. 31Níbẹ̀ ni èmi yóò ti ṣe ìdájọ́ yín, èmi o sì fi èémí ìbínú gbígbóná mi bá yín jà. 32Ẹ̀yin yóò jẹ́ èpò fún iná náà, a yóò ta ẹ̀jẹ̀ yin sórí ilẹ̀ yín, a kì yóò rántí yín mọ́; nítorí Èmi Olúwa ní ó ti wí bẹ́ẹ̀.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.