Native Bible

Ezekiel 21:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Ìwọ aláìmọ́ àti ẹni búburú ọmọ-aládé Israẹli, ẹni ti ọjọ́ rẹ̀ ti dé, ẹni tí àsìkò ìjìyà rẹ̀ ti dé góńgó,

Ezekiel 21:25 in English

Ezekiel 21:25 · Berean Standard Bible

And you, O profane and wicked prince of Israel, the day has come for your final punishment.’

Context

23Àfọ̀ṣẹ náà yóò dàbí àmì èké sí àwọn tí ó ti búra ìtẹríba fún un, ṣùgbọ́n òun yóò ran wọn létí ẹbí wọn yóò sì mú wọn lọ sí ìgbèkùn. 24“Nítorí náà èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí ti ẹ̀yin ti mú ẹ̀bi yín wá sí ìrántí nípa ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba, ní ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí, a yóò mú yín ní ìgbèkùn. 25“ ‘Ìwọ aláìmọ́ àti ẹni búburú ọmọ-aládé Israẹli, ẹni ti ọjọ́ rẹ̀ ti dé, ẹni tí àsìkò ìjìyà rẹ̀ ti dé góńgó, 26èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀, ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀. 27Ìparun! Ìparun! Èmi yóò ṣé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò ṣe pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fi fún.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.