Oniwaasu 5:14
Ecclesiastes 5:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tàbí ọrọ̀ tí ó sọnù nípa àìrí ojúrere, nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún un.
Ecclesiastes 5:14 in English
Ecclesiastes 5:14 · Berean Standard Bible
or wealth lost in a failed venture, so when that man has a son there is nothing to pass on.
Context
12Oorun alágbàṣe a máa dùn,
yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀,
ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀
kì í jẹ́ kí ó sùn rárá. 13Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn
ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun ẹni tó ni nǹkan. 14Tàbí ọrọ̀ tí ó sọnù nípa àìrí ojúrere,
nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin
kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún un. 15Ìhòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀,
bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúrò
kò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀
tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀. 16Ohun búburú gbá à ni eléyìí pàápàá.
Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọ
kí wá ni èrè tí ó jẹ
nígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.