Oniwaasu 5:16
Ecclesiastes 5:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ohun búburú gbá à ni eléyìí pàápàá. Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọ kí wá ni èrè tí ó jẹ nígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́?
Ecclesiastes 5:16 in English
Ecclesiastes 5:16 · Berean Standard Bible
This too is a grievous evil: Exactly as a man is born, so he will depart. What does he gain as he toils for the wind?
Context
14Tàbí ọrọ̀ tí ó sọnù nípa àìrí ojúrere,
nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin
kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún un. 15Ìhòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀,
bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúrò
kò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀
tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀. 16Ohun búburú gbá à ni eléyìí pàápàá.
Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọ
kí wá ni èrè tí ó jẹ
nígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́? 17Ó ń jẹ nínú òkùnkùn ní gbogbo ọjọ́ ọ rẹ̀,
pẹ̀lú iyè ríra tí ó ga, ìnira àti ìbínú. 18Nígbà náà ni mo wá rí i dájú pé, ó dára, ó sì tọ̀nà fún ènìyàn láti jẹ, kí ó mu, kí ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ̀ lábẹ́ oòrùn, ní àkókò ọjọ́ ayé díẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún un, nítorí ìpín rẹ̀ ni èyí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.