Oniwaasu 5:17
Ecclesiastes 5:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó ń jẹ nínú òkùnkùn ní gbogbo ọjọ́ ọ rẹ̀, pẹ̀lú iyè ríra tí ó ga, ìnira àti ìbínú.
Ecclesiastes 5:17 in English
Ecclesiastes 5:17 · Berean Standard Bible
Moreover, all his days he eats in darkness, with much sorrow, sickness, and anger.
Context
15Ìhòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀,
bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúrò
kò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀
tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀. 16Ohun búburú gbá à ni eléyìí pàápàá.
Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọ
kí wá ni èrè tí ó jẹ
nígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́? 17Ó ń jẹ nínú òkùnkùn ní gbogbo ọjọ́ ọ rẹ̀,
pẹ̀lú iyè ríra tí ó ga, ìnira àti ìbínú. 18Nígbà náà ni mo wá rí i dájú pé, ó dára, ó sì tọ̀nà fún ènìyàn láti jẹ, kí ó mu, kí ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ̀ lábẹ́ oòrùn, ní àkókò ọjọ́ ayé díẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún un, nítorí ìpín rẹ̀ ni èyí. 19Síwájú sí, nígbà tí Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni ní ọrọ̀ àti ohun ìní, tí ó sì fún un lágbára láti gbádùn wọn, láti gba ìpín rẹ̀ kí inú rẹ̀ sì dùn sí iṣẹ́ rẹ—ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.