Native Bible

Ecclesiastes 5:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun ẹni tó ni nǹkan.

Ecclesiastes 5:13 in English

Ecclesiastes 5:13 · Berean Standard Bible

There is a grievous evil I have seen under the sun: wealth hoarded to the harm of its owner,

Context

11Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ sí i, náà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ sí i Èrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí ẹni tí ó ni nǹkan bí kò ṣe pé, kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rí rí wọn? 12Oorun alágbàṣe a máa dùn, yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn rárá. 13Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun ẹni tó ni nǹkan. 14Tàbí ọrọ̀ tí ó sọnù nípa àìrí ojúrere, nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún un. 15Ìhòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀, bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúrò kò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.