Oniwaasu 5:12
Ecclesiastes 5:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Oorun alágbàṣe a máa dùn, yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn rárá.
Ecclesiastes 5:12 in English
Ecclesiastes 5:12 · Berean Standard Bible
The sleep of the worker is sweet, whether he eats little or much, but the abundance of the rich man permits him no sleep.
Context
10Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító,
ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn
pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún un. 11Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ sí i,
náà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ sí i
Èrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí ẹni tí ó ni nǹkan bí kò ṣe pé,
kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rí rí wọn? 12Oorun alágbàṣe a máa dùn,
yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀,
ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀
kì í jẹ́ kí ó sùn rárá. 13Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn
ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun ẹni tó ni nǹkan. 14Tàbí ọrọ̀ tí ó sọnù nípa àìrí ojúrere,
nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin
kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.