Native Bible

Ecclesiastes 5:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító, ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún un.

Ecclesiastes 5:10 in English

Ecclesiastes 5:10 · Berean Standard Bible

He who loves money is never satisfied by money, and he who loves wealth is never satisfied by income. This too is futile.

Context

8Bí o bá rí tálákà tí wọ́n ń ni lára ní ojú púpọ̀, tí a sì ń fi òtítọ́ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu láti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹni tí ó wà ní ipò gíga máa ń mọ́ òṣìṣẹ́ tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ lójú ni, síbẹ̀ àwọn kan sì wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn méjèèjì. 9Gbogbo wọn ni ó ń pín èrè tí wọ́n bá rí lórí ilẹ̀, àní ọba pàápàá ń jẹ èrè lórí oko. 10Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító, ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún un. 11Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ sí i, náà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ sí i Èrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí ẹni tí ó ni nǹkan bí kò ṣe pé, kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rí rí wọn? 12Oorun alágbàṣe a máa dùn, yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn rárá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.