Oniwaasu 5:11
Ecclesiastes 5:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ sí i, náà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ sí i Èrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí ẹni tí ó ni nǹkan bí kò ṣe pé, kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rí rí wọn?
Ecclesiastes 5:11 in English
Ecclesiastes 5:11 · Berean Standard Bible
When good things increase, so do those who consume them; what then is the profit to the owner, except to behold them with his eyes?
Context
9Gbogbo wọn ni ó ń pín èrè tí wọ́n bá rí lórí ilẹ̀, àní ọba pàápàá ń jẹ èrè lórí oko. 10Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító,
ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn
pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún un. 11Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ sí i,
náà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ sí i
Èrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí ẹni tí ó ni nǹkan bí kò ṣe pé,
kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rí rí wọn? 12Oorun alágbàṣe a máa dùn,
yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀,
ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀
kì í jẹ́ kí ó sùn rárá. 13Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn
ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun ẹni tó ni nǹkan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.