Sefaniah 2:10
Zephaniah 2:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà padà nítorí ìgbéraga wọn, nítorí wọ́n kẹ́gàn, wọn sì ti fi àwọn ènìyàn Olúwa àwọn ọmọ-ogun ṣe ẹlẹ́yà.
Zephaniah 2:10 in English
Zephaniah 2:10 · Berean Standard Bible
This they shall have in return for their pride, for taunting and mocking the people of the LORD of Hosts.
Context
8“Èmi ti gbọ́ ẹ̀gàn Moabu,
àti ẹlẹ́yà àwọn Ammoni,
àwọn tó kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi,
tí wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí agbègbè wọn. 9Nítorí náà, bí Èmi tí wà,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
Ọlọ́run àwọn Israẹli wí,
“nítòótọ́ Moabu yóò dàbí Sodomu,
àti Ammoni yóò sì dàbí Gomorra,
ibi tí ó kún fún yèrèpè,
àti ìhó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé.
Ìyókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn;
àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi ni yóò jogún ilẹ̀ wọn.” 10Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà padà nítorí ìgbéraga wọn,
nítorí wọ́n kẹ́gàn, wọn sì ti fi àwọn ènìyàn Olúwa àwọn ọmọ-ogun ṣe ẹlẹ́yà. 11Olúwa yóò jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn;
nígbà tí Òun bá pa gbogbo òrìṣà ilẹ̀ náà run.
Orílẹ̀-èdè láti etí odò yóò máa sìn,
olúkúlùkù láti ilẹ̀ rẹ̀ wá. 12“Ẹ̀yin Etiopia pẹ̀lú,
a ó fi idà mi pa yín.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.