Sefaniah 2:12
Zephaniah 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ̀yin Etiopia pẹ̀lú, a ó fi idà mi pa yín.”
Zephaniah 2:12 in English
Zephaniah 2:12 · Berean Standard Bible
“You too, O Cushites,* will be slain by My sword.”
Context
10Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà padà nítorí ìgbéraga wọn,
nítorí wọ́n kẹ́gàn, wọn sì ti fi àwọn ènìyàn Olúwa àwọn ọmọ-ogun ṣe ẹlẹ́yà. 11Olúwa yóò jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn;
nígbà tí Òun bá pa gbogbo òrìṣà ilẹ̀ náà run.
Orílẹ̀-èdè láti etí odò yóò máa sìn,
olúkúlùkù láti ilẹ̀ rẹ̀ wá. 12“Ẹ̀yin Etiopia pẹ̀lú,
a ó fi idà mi pa yín.” 13Òun yóò sì na ọwọ́ rẹ̀ sí apá àríwá,
yóò sì pa Asiria run,
yóò sì sọ Ninefe di ahoro,
àti di gbígbẹ bí aginjù. 14Agbo ẹran yóò sì dùbúlẹ̀ ni àárín rẹ̀,
àti gbogbo ẹranko àwọn orílẹ̀-èdè.
Òwìwí aginjù àti ti n kígbe ẹyẹ òwìwí
yóò wọ bí ẹyẹ ni ọwọ̀n rẹ̀.
Ohùn wọn yóò kọrin ni ojú fèrèsé,
ìdahoro yóò wà nínú ìloro ẹnu-ọ̀nà,
òun yóò sì ṣẹ́ ọ̀pá kedari sílẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.