Native Bible

Zephaniah 2:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, bí Èmi tí wà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí, “nítòótọ́ Moabu yóò dàbí Sodomu, àti Ammoni yóò sì dàbí Gomorra, ibi tí ó kún fún yèrèpè, àti ìhó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé. Ìyókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn; àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi ni yóò jogún ilẹ̀ wọn.”

Zephaniah 2:9 in English

Zephaniah 2:9 · Berean Standard Bible

Therefore, as surely as I live,” declares the LORD of Hosts, the God of Israel, “surely Moab will be like Sodom and the Ammonites like Gomorrah— a place of weeds and salt pits, a perpetual wasteland. The remnant of My people will plunder them; the remainder of My nation will dispossess them.”

Context

7Agbègbè náà yóò sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ilé Juda, níbẹ̀ ni wọn yóò sì ti rí koríko fún ẹran. Ní ilé Aṣkeloni ni wọn yóò dùbúlẹ̀ ni àṣálẹ́. Olúwa Ọlọ́run wọn yóò bẹ̀ wọn wò, yóò sì yí ìgbèkùn wọn padà. 8“Èmi ti gbọ́ ẹ̀gàn Moabu, àti ẹlẹ́yà àwọn Ammoni, àwọn tó kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí agbègbè wọn. 9Nítorí náà, bí Èmi tí wà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí, “nítòótọ́ Moabu yóò dàbí Sodomu, àti Ammoni yóò sì dàbí Gomorra, ibi tí ó kún fún yèrèpè, àti ìhó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé. Ìyókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn; àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi ni yóò jogún ilẹ̀ wọn.” 10Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà padà nítorí ìgbéraga wọn, nítorí wọ́n kẹ́gàn, wọn sì ti fi àwọn ènìyàn Olúwa àwọn ọmọ-ogun ṣe ẹlẹ́yà. 11Olúwa yóò jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn; nígbà tí Òun bá pa gbogbo òrìṣà ilẹ̀ náà run. Orílẹ̀-èdè láti etí odò yóò máa sìn, olúkúlùkù láti ilẹ̀ rẹ̀ wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.