Sefaniah 2:7
Zephaniah 2:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Agbègbè náà yóò sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ilé Juda, níbẹ̀ ni wọn yóò sì ti rí koríko fún ẹran. Ní ilé Aṣkeloni ni wọn yóò dùbúlẹ̀ ni àṣálẹ́. Olúwa Ọlọ́run wọn yóò bẹ̀ wọn wò, yóò sì yí ìgbèkùn wọn padà.
Zephaniah 2:7 in English
Zephaniah 2:7 · Berean Standard Bible
The coast will belong to the remnant of the house of Judah; there they will find pasture. They will lie down in the evening among the houses of Ashkelon, for the LORD their God will attend to them and restore their captives.*
Context
5Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń gbé etí Òkun,
ẹ̀yin ènìyàn ara Kereti;
ọ̀rọ̀ Olúwa dojúkọ ọ́, ìwọ Kenaani,
ilẹ̀ àwọn ara Filistini.
“Èmi yóò pa yín run,
ẹnìkan kò sì ní ṣẹ́kù nínú yín.” 6Ilẹ̀ náà ní etí Òkun, ni ibùgbé àwọn ará Kereti,
ni yóò jẹ́ ibùjókòó fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti agbo àgùntàn. 7Agbègbè náà yóò sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ilé Juda,
níbẹ̀ ni wọn yóò sì ti rí koríko fún ẹran.
Ní ilé Aṣkeloni ni wọn yóò
dùbúlẹ̀ ni àṣálẹ́.
Olúwa Ọlọ́run wọn yóò bẹ̀ wọn wò,
yóò sì yí ìgbèkùn wọn padà. 8“Èmi ti gbọ́ ẹ̀gàn Moabu,
àti ẹlẹ́yà àwọn Ammoni,
àwọn tó kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi,
tí wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí agbègbè wọn. 9Nítorí náà, bí Èmi tí wà,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
Ọlọ́run àwọn Israẹli wí,
“nítòótọ́ Moabu yóò dàbí Sodomu,
àti Ammoni yóò sì dàbí Gomorra,
ibi tí ó kún fún yèrèpè,
àti ìhó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé.
Ìyókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn;
àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi ni yóò jogún ilẹ̀ wọn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.