Native Bible

Song of Songs 6:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì, láti rí i bí àjàrà rúwé, tàbí bí pomegiranate ti rudi.

Song of Songs 6:11 in English

Song of Songs 6:11 · Berean Standard Bible

I went down to the walnut grove to see the blossoms of the valley, to see if the vines were budding or the pomegranates were in bloom.

Context

9Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni, ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ̀, ààyò ẹyọ kan ṣoṣo ẹni tí ó bí i. Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fún un. 10Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀, tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn, tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun? 11Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì, láti rí i bí àjàrà rúwé, tàbí bí pomegiranate ti rudi. 12Kí èmi tó mọ̀, àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàrín àwọn ènìyàn mi. 13Padà wá, padà wá, ìwọ ọmọ Ṣulamati; padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.